Revelation of John 6:2-8

2 aMo sì wò ó, kíyèsi i, ẹṣin funfun kan: ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọfà kan; a sì fi adé kan fún un: ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìṣẹ́gun.

3Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!” 4Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde: a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn: A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́.

5Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. 6 bMo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òṣùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.

7Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó. 8 cMo sì wò ó, kíyèsi, ẹṣin ràndànràndàn kan: orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdámẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa.

Copyright information for YorBMYO